Posts

Showing posts from 2014

Onigbagbo E Bu Sayo

Author: John E. Bowers Onigbagbo e bu sayo! Ojo nla loni fun wa Korun fayo korin kikan, Kigbo atodan gberin E ho! E yo! Okun atodo gbogbo. E jumo yo, gbogbo eda, Laye yi ati lorun, Ki gbogbo ohun alaaye Nile, loke, yin Jesu E fogo fun Oba nla ta bi loni. Gbohun yin ga, "Om'Afrika" Eyin iran Yoruba; Ke "Hosanna" lohun gooro Jake jado ile wa. Koba gbogbo, Juba Jesu Oba wa. E damuso! E damuso! E ho ye! Ke si ma yo, Itegun Esu fo wayi, "Iru-omobinrin" de. Halleluyah! Olurapada, Oba. E gbohun yin ga, Serafu, Kerubu, leba ite; Angeli ateniyan mimo, Pelu gbogbo ogun orun. E ba wa yo! Odun idasile de. Metalokan, Eni Mimo Baba Olodumare Emi Mimo, Olutunnu, Jesu, Olurapada, Gba iyin wa 'Wo nikan logo ye fun. Christians lift your voice in praises On this memorable day Sing in gladness, let your voices Sing all over vale and dale Laud Hosannas, laud Hosannas, Sea and streams all join the strain. Come ye peo

WA EYIN OLOOTO

Words: John Francis Wade Wa eyin olooto Layo ati'segun Wa kalo, wa kalo si Betlehem Wa ka lo wo o! Oba awon Angeli! E wa ka lo juba Re/2X E wa ka lo juba Kristi Oluwa Olodumare ni, Imole Ododo, Ko si korira inu wundia; Olorun paapaa ni Ti a bi, ti a ko da; Angeli, e korin, Korin itoye Re, Ki gbogbo eda orun si gberin: Ogo f'Olorun Li oke orun, Nitooto, a wole F'Oba ta bi loni; Jesu, Iwo lawa n fi ogo fun, 'Wo Omo Baba, T'O mara wa wo! O come, all ye faithful, joyful and triumphant! O come ye, O come ye to Bethlehem! Come and behold him, born the King of angels; O come, let us adore him, O come, let us adore him, O come, let us adore him, Christ the Lord! God of God, Light of Light eternal, lo, he abhors not the virgin’s womb; Son of the Father, begotten, not created; Sing, choirs of angels, sing in exultation, sing, all ye citizens of heaven above: “Glory to God, all glory in the highest!” Yea, Lord, we greet thee, bor

GBO OHUN ALORE

Words: Horatius Bonar Gbo ohun alore, Ji, ara, ji; Jesu ma fere de, Ji, ara, ji, Omo oru ni sun, Omo imole leyin, Ti yin logo didan, Ji, ara, ji. So fegbe to ti ji, Ara, sora; Ase Jesu daju, Ara, sora; E se b'olusona Nilekun Oluwa yin Bi O tile pe de, Ara, sora. Gbo ohun iriju, Ara, sise; Ise na kari wa, Ara, sise; Ogba Oluwa wa, Kun fun'se nigba gbogbo Yoo si fun wa lere, Ara sise. Gbo ohun Oluwa wa, E gbadura; Be fe kinu Re dun E gbadura; Ese 'mu beru wa, Alailera si ni wa; Ni ijakadi yin, E gbadura Ko orin ikehin, Yin, ara, yin; Mimo ni Oluwa. Yin, ara, yin: Ki lo tun ye ahon, To fere b'Angel' korin, T'y'o ro lorun titi, Yin, ara, yin. Hark! ’tis the watchman’s cry, Wake, brethren, wake! Jesus our Lord is nigh; Wake, brethren, wake! Sleep is for sons of night; Ye are children of the light, Yours is the glory bright; Wake, brethren, wake! Call to each waking band, Watch, brethren, watch! Clear is

Aajin Jin, Oru Mimo

Words: Joseph Mohr Aajin jin, oru mimo, Ookun su, mole de, Awon Olus'aguntan n sona, Omo to wa loju orun,   Sinmi n'nu alafia   Sinmi n'nu alafia. Aajin jin, oru mimo, Mole de, ookun sa, Oluso aguntan gborin Angel', Kabiyesi aleluya Oba.   Jesu Olugbala de   Jesu Olugbala de. Aajin jin, oru mimo, 'Rawo orun tan mole Wo awon Amoye ila orun Mu ore won wa fun Oba wa,   Jesu Olugbala de   Jesu Olugbala de. Aajin jin, oru mimo, 'Rawo orun tan 'mole Ka pelu awon Angel korin, Kabiyesi aleluya Oba   Jesu Olugbala de   Jesu Olugbala de. Silent night! Holy night! All is calm, all is bright ’round yon virgin mother and child! Holy infant, so tender and mild, sleep in heavenly peace, sleep in heavenly peace. Silent night! Holy night! Shepherds quake at the sight. Glories stream from heaven afar, heavenly hosts sing: “Alleluia! Christ the Savior is born! Christ the Savior is born!” Silent night! Holy night! Son of God, love

O De

O de, Kristi Oluwa, Lat'ibugbe Re lorun, Lat'ite alafia, O wa si aginju wa. Alade Alana De lati ru 'ponju wa; O de, lati f'imole, Le okun oru wa lo. Jesus Christ the Lord has come, From His Father's throne above. From above the throne of peace. He came to this wilderness. Christ the Lord the Prince of Peace Come to bear all our burden, He has come to give us light, Drives away all our nightmare. Source: Hymnaro #92 Aroyehun ©2013

Wo Oju Sanma

Wo oju sanma ohun ni, Wo lila orun ooro; Ji loju orun, okan mi, Dide ko si ma sora; Olugbala Tun n pada bo wa saye. Ope ti mo ti n reti Re, L'are lokan mi n duro, Aye ko ni ayo fun mi, Nibi ti ko tan 'mole, Olugbala, 'Gbawo n'Iwo o pada? Igbala mi sunm' etile, Oru fere koja na, Je ki n wa nipo irele, Ki n s'afojusona Re, Olugbala Titi n o fi roju Re. Je ki fitila mi ma jo, Ki n ma sako kiri mo, Ki n sa ma reti abo Re, Lati mu mi lo sile; Olugbala Yara k'O ma bo kankan. Behold, see yonder horizon Behold the morning sunrise Wake from thy deep sleep, thou my heart Arise and be thou watchful; Blessed Saviour, blessed Saviour Coming again to the earth It's long I've been expecting Thee My weary heart long doth wait The world has no more joy for me, E'er its light has become dark Blessed Saviour, blessed Saviour, When will Thou come back again My salvation doth draw nearer The dark night is almost gone Let

Ma Wole, Jesu Ta N Reti

Ma wole, Jesu ta n reti, Ta bi lati gba ni la! Gba wa low'ese ate'eru; Ka ri'sinmi ninu Re. Ipa ati'tunu Israel', Ireti awon mimo; Olufe gbogbo orile, Ayo okan ti n reti. A bi O lati gbeda la, Eniyan--sugbon Olorun-- Lati joba lai ninu wa, Mu 'joba rere re wa. Nipa Emi Re to wa lai, Nikan joba ninu wa; Nipa 'toye Re to po to Gbe wa site ogo Re. Long expected, our Lord Jesus, Born to give us salvation, Redeem us from fear and sin Give us peace eternally/2x Pow’r, peace and joy for Israel, The hope of righteous men, Lover of the entire nations; Joy for the expectant souls/2x Born to give us salvation, God born of human flesh To reign in heart for ever, Send down Thou good governance/2x By the Spirit forever more, Reign forever in our souls By the great mercies forever, Reign with You all ever more /2x Source: Hymnaro #88 Aroyehun ©2013

AYO BAYE

Words: Isaac Watts (1674-1748), 1719 Ayo baye: Oluwa de! Kaye gba Oba re; Kokan gbogbo pes'aye fun Un, Ki gbogbo eda korin. Ayo baye: Jesu joba; Ki eniyan korin; Gbati ohun gbogbo laye Tun n ro iro iro ayo. Kese at'ikanu ye wa Kile ye hu egun; O wa lati da ibukun Sori egun gbogbo. O n fotito joba laye, O si m' oril 'ede Jeri ogo at'oto Re, At'iyanu 'fe Re. Joy to the world! the Lord is come: let earth receive her King; let every heart prepare him room, and heaven and nature sing. Joy to the world! the Savior reigns; let us our songs employ, while fields and floods, rocks, hills and plains repeat the sounding joy. No more let sins and sorrows grow, nor thorns infest the ground; he comes to make his blessings flow far as the curse is found. He rules the world with truth and grace, and makes the nations prove the glories of his righteousness, and wonders of his love.

Igbagbo Mi N Wo O

Words: Ray Palmer, 1830 Igbagbo mi n wo O, Iwo Od'Aguntan, Olugbala, Jo, gbo adura mi Mese mi gbogbo lo Kemi latoni lo si je tire. Ki ore-ofe Re, Filera fokan mi, Mu mi tara; Biwo ti ku fun mi, A! kife mi si O, Ko ma gbona titi, Ina iye. Gba mo rin lokunkun, Tibinu yi mi ka, Samona mi, Mokunkun lo loni, N'omije anu nu, Lai, ma je ki n sako Li odo Re. Gbati aye ba pin, Todo tutu iku, Nsan lori mi: Jesu, ninu ife, Mu kifoya mi lo, Gbe mi doke orun Bokan ta ra. My faith looks up to Thee, Thou Lamb of Calvary, Savior divine! Now hear me while I pray, take all my guilt away, O let me from this day be wholly Thine! May Thy rich grace impart Strength to my fainting heart, my zeal inspire! As Thou hast died for me, O may my love to Thee, Pure warm, and changeless be, a living fire! While life’s dark maze I tread, And griefs around me spread, be Thou my guide; Bid darkness turn to day, wipe sorrow’s tears away, Nor let me ever stray from

Bibeli Mimo Torun

Words: John Burton, Sr., Youth’s Mon­i­tor in Verse, 1803. Bibeli mimo torun Owon isura temi! 'Wo ti n wi bi mo ti ri, 'Wo ti n so bi mo ti wa. 'Wo nko mi, bi mo sina, 'Wo n f'ife Oluwa han; 'Wo lo si n to ese mi, 'Wo lo n dare at'ebi. 'Wo ni ma tu wa ninu, Ninu wahala aye, 'Wo n ko ni, nipa 'gbagbo Pe a le segun iku. 'Wo lo n so tayo ti n bo, Ati 'parun elese; Bibeli mimo torun, Owon isura temi. Holy Bible, Book divine, Precious treasure, thou art mine; Mine to tell me whence I came; Mine to teach me what I am. Mine to chide me when I rove; Mine to show a Savior’s love; Mine thou art to guide and guard; Mine to punish or reward. Mine to comfort in distress; Suffering in this wilderness; Mine to show, by living faith, Man can triumph over death. Mine to tell of joys to come, And the rebel sinner’s doom; O thou holy Book divine, Precious treasure, thou art mine.

Itan Iyanu Tife

Author: J. M. Driver (1892) Itan iyanu tife! So fun mi leekan si, Itan iyanu tife! Ti n dun leti kikan! Awon angeli rohin re, awon oluso si gbagbo, Elese iwo ki yoo gbo, itan iyanu tife? Iyanu!/3X Itan iyanu tife! Itan iyanu tife! Biwo tile sako Itan iyanu tife!Sibe o n pe loni; Latori oke Kalfari, lati orisun Krystali; Lat isedale aye; Itan iyanu tife! Itan iyanu tife! Jesu ni isimi; Itan iyanu tife! Fun awon olooto, To sinmi nilu nla orun, pel' awon to saju wa lo; Won n kan orin ayo orun: Itan iyanu tife! Wonderful story of love; Tell it to me again; Wonderful story of love; Wake the immortal strain! Angels with rapture announce it, Shepherds with wonder receive it; Sinner, oh, won’t you believe it? Wonderful story of love. Wonderful! Wonderful! Wonderful, wonderful story of love. Wonderful story of love; Though you are far away; Wonderful story of love; Still He doth call today; Calling from Calvary’s mountain, Down from the crystal-br

O N To Mi Lo

Author: Gilmore, Joseph Henry O n to mi lo iro 'bukun, Oro torun tu mi ninu, Ohun ti o wu kemi se Sibe Olorun n to mi lo. Refrain: O n to mi lo, O n to mi lo, Owo Re lo fi n to mi lo, Lotito ni mo fe tele E Nitoriti O n to mi lo Nigba miran tiponju wa, Nigba miiran logba Eden Leba odo lokun 'ponju, Sibe Olorun n to mi lo. Oluwa mo dowo Re mu N ko ni kun, n ko ni ibanuje, Fohun 'yowu ti mo le ri Niwon t'Olorun mi n to mi Nigba 'se mi laye ba pin, Toor'ofe Re fun mi nisegun, Emi ko ni beru iku, Niwon t'Olorun mi n to mi. Source: YBH #606 He leadeth me! O blessed thought, O words with heav’nly comfort fraught; Whate’er I do, where’er I be, Still ’tis Christ’s hand that leadeth me. He leadeth me, he leadeth me; by his own hand he leadeth me: his faithful follower I would be, for by his hand he leadeth me. Sometimes mid scenes of deepest gloom, sometimes where Eden's flowers bloom, by waters calm, o'er troubled

To Won Baba Si O

Author Unknown To won, Baba si O, To won si O; Awon omo wonyi Ti O fun ni, Nipa 'fe Re orun, To won Baba si O, To won, Baba si O, To won si O. Gbati aye ba n dan Ko won lona Re, Ma je kohun etan Mu won sina. Kuro nipa 'danwo To won Baba si O, To won, Baba si O, To won si O. Fun 'ru won ni Jesu Wa lomode, O si gbaye ese Lailabawon; A! 'Tori Re ma sai To won Baba si O, To won, Baba si O, To won si O. 'Gbagbo mi le sai pe Sibe mo mo Pawon ore wonyi 'Wo yoo gba won; A! Gb' okan won sodo Ko si to won si O To won, Baba si O, To won si O. Source: YBH #430 (I adjusted line 2 of verse 2) Guide them, Father to thee, guide them to Thee All these thy great children, that Thou giveth Lord, By Thy heav'nly love, Guide them Father to Thee Guide them, Father to thee, guide them to Thee When this life is sweet, train them Thy way, Let not deceitful treasure mislead them all, Away from temptation, guide them Father to Thee

JESU NI BALOGUN OKO

Image
Author Unknown Jesu ni Balogun oko E mase je ka foya Olutoko wa ni Jesu Y'o mu oko wa gunle Refrain: E ma se beru E kun fun ayo Nitori Jesu l'oga oko Bo ti wu k'iji na le to Y'o mu oko wa gunle Eyin ero t'o wa l'oko E kepe Jesu nikan K'e si gbeke yin le Jesu Y'o mu oko wa gunle Olugbala 'wa toro Re Mu igb'omi pa roro Iwo t'o rin lori omi T'o sun, beni ko si nkan Kil' ohun to nba yin leru Eyin omo 'gun Kristi Bi Jesu ba wo ' nu oko Awa y'o fi 'gbi rerin 'Gbati 'gbi aye yi ba nja Lor' okun ati n'ile Abo kan mbe ti o daju Lodo Olugbala wa Lowo kiniun at' ekun Lowo eranko ibi Jesu y'o dabobo Tire Jesu y'o pa Tire mo Metalokan Alagbara Dabobo awa omo Re Lowo a'tegun ati 'ji Je k'awa k' alleluyah Ogo ni fun Baba loke Ogo ni fun Omo Re Ogo ni fun Emi Mimo Metalokan l'ope ye. Jesus is the Captain of the ship, So, do no let us

Aye Si N Be Nile Od'aguntan

Words: Horatius Bonar (1808-1889), 1872 Music: Cantus (Uzziah C. Burnap, 1895) Aye si n be nile Od'agutan Ewa ogo Re n pe O pe ma bo Wole, wole, wole nisisiyi Ojo lo tan, orun si fere wo, Okunkun de tan, mole n koja lo Wole, wole, wole nisisiyi Ile iyawo na kun fun ase! Wole, wole to Oko 'yawo: Wole, wole, wole nisisiyi. "Aye si n be!" ilekun si sile, Ilekun ife: iwo ko pe ju, Wole, wole, wole nisisiyi Wa gbebun 'fe ayeraye lofe! Wole, wole, wole nisisiyi. Kiki ayo lo wa nibe, wole! Awon Angel lo npe o fun ade; Wole, wole, wole nisisiyi. Lohun rara nipe ife naa ndun! Wa, ma jafara, wole ase naa. Wole, wole, wole nisisiyi. O n kun, o n kun! Ile ayo na n kun! Yara! mase pe, ko kun ju fun o. Wole, wole, wole nisisiyi. Kile to su, ilekun na le ti! 'Gbana, o kabamo! "O se! O se!" O se! O se! Ko saye mo, o se! "Yet there is room": the Lamb's bright hall of song, With its fair glory, beckons thee along;

FUN MI NIWA PELE

Fun mi niwa pele, okan tutu; Ifarabale bi toluwa mi; Irele o'n suuru atopo iyonu Ninu ohun gbogbo ki n jo Jesu. Fun mi nitelorun nipokipo Ko le rele juyi ta bi Jesu Fun mi nitunu Re atiranlowo Re Ninu ohun gbogbo, ki n jo Jesu. Fun mi ni itara sipa Tire; Aniyan atife sohun torun Fun mi niwa mimo, ikorira ese Ninu ohun gbogbo ki n jo Jesu. Fun mi ni igbagbo atireti Fun mi layo'gbala ninu Jesu; Femi iye fun mi, fun mi lade ogo 'Gbati mo ba jinde ki n jo Jesu. Give me a gentle heart filled with meekness diligent heart like thine Jesus, my lord humbleness and patience a heart of compassion, in every small detail to be like him. Give me contentment in all conditions be it even humbler than his lowly birth give me thou thy comfort give me also thy help in every small detail to be like him. Give me enthusiasm in things of thine earnestness and more love for things of heaven give me a holy heart give me hatred for sin in every small de

Mo Fe Ki N Dabi Jesu

Author: W. Meynell Whittemore  Mo fe ki n dabi Jesu Ninu iwa pele Ko seni to gboro 'binu Lenu Re lekan ri. Mo fe ki n dabi Jesu, Ladura n'gbagbogbo Lori oke ni Oun nikan Lo pade Baba Re. Mo fe ki n dabi Jesu, Emi ko ri ka pe Bi won ti korira Re to O senikan nibi. Mo fe ki n dabi Jesu Ninu ise rere Ka le wi nipa temi pe, "O se'won to le se" Mo fe ki ndabi Jesu To fiyonu wipe "Je komode wa sodo mi" Mo fe je ipe Re. Sugbon n ko dabi Jesu O si han gbangba be; Jesu fun mi lore-ofe Se mi ki n dabi Re. I want to be like Jesus, So lowly and so meek, For no one marked an angry word That every heard Him speak. I want to be like Jesus, So frequently in prayer; Alone upon the mountain-top, He met His Father there. I want to be like Jesus, I never, never find That He, though persecuted, was To any one unkind. I want to be like Jesus, Engaged in doing good, So that of me it may be said, `She hath done what she could

Olorun Odun To Koja

Words: Isaac Watts (1674-1748), 1719 Olorun odun to koja, Iret'eyi ti nbo: Ib'isadi wa ni iji, Atile wa lailai. Labe ojiji ite Re lawon eniyan Re n gbe! Tito lagbara Re nikanso Abo wa si daju. Kawon oke ko to duro Tabi ka to daye Lailai Iwo ni Olorun Bakanna, lailopin. Egberun odun loju Re Bi ale kan lo rí; B'iso kan l'afemojumo Kí oorun ko to la. Ojo wa bi odo sisan, Opo lo si n gbe lo; Won n lo, won di eni  'gbagbe Bi ala ti a n ro. A mu eje a'tebe wa Wa si waju 'te Re Iwo yio je Olorun wa A t'ipin wa lailai Olorun odun to koja Iret'eyi ti nbo: Ib'isadi wa ni iji, Atile wa lailai. O God, our help in ages past, our hope for years to come, our shelter from the stormy blast, and our eternal home: Under the shadow of thy throne, thy saints have dwelt secure; sufficient is thine arm alone, and our defense is sure. Before the hills in order stood, or earth received her frame, from everlasting thou ar

GBORI RE SOKE ALAARE

Image
Mary M. Weinland, 1887 Gbori re soke alare Tori ayo n bo lowuro Olorun so n'nu oro Re Pe ayo ma n bo lowuro Refrain: Ayo ma n bo lowuro/2x Ekun le pe titi dale Sugbon ayo n bo lowuro Eyin mimo ma beru mo Tori ayo n bo lowuro Eyin olofo nuju nu Tori ayo n bo lowuro E yo oru fere koja Tori ayo n bo lowuro Ooro to logo yoo si de Tori ayo n bo lowuro Ki gbogbo wa ma yo loni Tori ayo n bo lowuro Olorun yoo n'omije nu Tori ayo n bo lowuro Oh, weary pilgrim, lift your head: For joy cometh in the morning! For God in His own Word hath said That joy cometh in the morning! Joy cometh in the morning! Joy cometh in the morning! Weeping may endure for a night, But joy cometh in the morning! Ye trembling saints, dismiss your fears: For joy cometh in the morning! Oh, weeping mourner, dry your tears: For joy cometh in the morning! Let every burdened soul look up: For joy cometh in the morning! And every trembling sinner hope: For joy cometh in

NIPA IFE OLUGBALA

Words: Mary B. Peters Nigba ife Olugbala, Ki yo si nkan Oju rere Re ki pada Ki yo si nkan Owon l'Eje to wo wa san Pipe ledidi oor'ofe Agbara lowo to n gba ni Ko le si nkan Bi a wa ninu iponju Ki yo si nkan Igbala kikun ni tiwa Ki yo si nkan Igbekele Olorun dun Gbigbe ninu Kristi lere Emi si n so wa di mimo Ko le si nkan Ojo ola yio dara Ki yo si nkan 'Gbagbo le korin n'nu'ponju Ki yo si nkan A gbekele'fe Baba wa Jesu fun wa lohun gbogbo Ni yiye tabi ni kiku Ko le si nkan Through the love of God our Savior, All will be well; Free and changeless is His favor; All, all is well. Precious is the blood that healed us; Perfect is the grace that sealed us; Strong the hand stretched out to shield us; All must be well. Though we pass through tribulation, All will be well; Ours is such a full salvation; All, all is well. Happy still in God confiding, Fruitful, if in Christ abiding, Holy through the Spirit’s guiding, All must

Gbati Ipe Oluwa Ba Dun

Words & Music:   James M. Black , 1893 Gbati ipe Oluwa ba dun T'akoko ba si pin T'imole owuro mimo n tan lailai; Gbat'awon ta ti gbala Yo pejo soke odo naa, Gba ta n pe oruko lohun, n o wa nbe. Gba ta n pe oruko lohun Gba ta n pe oruko lohun Gba ta n pe oruko lohun Gba ta n pe oruko lohun N o wa nbe. Looro daradara tawon Oku mimo y'o dide Togo ajinde Jesu o je tiwon Gba t'awon ayanfe Re yo Pejo nile lok'orun, Gba ta n pe oruko lohun, n o wa nbe. Je ka sise f'Oluwa Latowuro titi dale Ka soro 'fe yanu ati'toju Re; Gbat aye ba dopin tise Wa Si pari nihin, Gba ta n pe oruko lohun, n o wa nbe. When the trumpet of the Lord shall sound, and time shall be no more, And the morning breaks, eternal, bright and fair; When the saved of earth shall gather over on the other shore, And the roll is called up yonder, I’ll be there. When the roll, is called up yon-der, When the roll, is called up yon-der, When the roll, is call

IWO HA N BERU P'OTA YOO SEGUN

Words: Ada Blenkhorn Iwo ha n beru p'ota yoo segun? Ookun su lode osi su ju ninu? Si ferese ati ilekun sile Je ki 'ran oorun wole Refrain: Je ki 'ran oorun wole/2x Si ferese ati ilekun sile Je ki 'ran oorun wole. Igbagbo re n kere 'nu 'ja tiwo fe? Olorun ko ha gbo adura re bi? Si ferese ati ilekun sile Je ki 'ran oorun wole Iwo fe fi ayo lo soke orun? Ko si oorun mo bi ko se imole? Si ferese ati ilekun sile Je ki 'ran oorun wole Do you fear the foe will in the conflict win? Is it dark without you—darker still within? Clear the darkened windows, open wide the door, Let a little sunshine in. Let a little sunshine in, Let a little sunshine in; Clear the darkened windows, Open wide the door, Let a little sunshine in. Does your faith grow fainter in the cause you love? Are your prayers unanswered by your God above? Clear the darkened windows, open wide the door, Let a little sunshine in. Would you go rejoicing in the

Adua Didun

Words: William W. Walford Adua didun,  adua didun To gbe mi lo kuro laye, Lo'waju ite Baba mi, Ki n so gbogbo edun mi fun: Nigba'banuje ataro Adua laabo fun okan mi; Emi si bo lowo Esu 'Gbati mo ba gbadua didun. Adua didun,  adua didun Iye re yo gbe ebe mi, Lo sod'Eni t'O seleri Lati  bukun okan adua. Bo ti ko mi ki n woju Re Ki n gbekele,  ki n si gbagbo, N o ko gbogb'aniyan mi le E Ni akoko adua didun. Adua didun,  adua didun Je ki n ma r'itunu re gba Titi n o fi doke Pisgah, Ti n o rile mi lookere. N o bo ago ara sile Lati jogun ainipekun; N o korin bi mo ti n fo lo, O digbose,  Adua didun. Sweet hour of prayer! sweet hour of prayer! that calls me from a world of care, and bids me at my Father's throne make all my wants and wishes known. In seasons of distress and grief, my soul has often found relief, and oft escaped the tempter's snare by thy return, sweet hour of prayer! Sweet hour of prayer! sweet hour o

Eyin Ero

Image
Words: Fanny Crosby, 1859. Music: William Bradbury, 1861 Eyin ero, nibo l'e nlo T' enyin t' opa lowo nyin? A nrin ajo mimo kan lo, Nipa ase Oba wa, Lori oke on petele, A nlo s' afin Oba rere, A nlo s' afin Oba rere, A nlo s' ile t' o dara, A nlo s' afin Oba rere, A nlo s' ile t' o dara. Eyin ero, e so fun ni, T' ireti ti enyin ni? Aso mimo, ade ogo Ni Jesu y'o fi fun wa; Omi iye l' a o ma mu; A o si b' Olorun wa gbe, A o si b' Olorun wa gbe, N' ile mimo didara A o si b' Olorun wa gbe, N' ile mimo didara. E ko beru ona t' e nrin, Eyin ero kekere? Ore airi npelu wa lo, Awon Angeli yi wa ka, Jesu Kristi l' amona wa; Y'o ma so wa, y'o ma to wa, Y'o ma so wa, y'o ma to wa, Ninu ona ajo wa; Y'o ma so wa, y'o ma to wa, Ninu ona ajo wa. Ero, a le ba yin kegbe, L' ona ajo s' ile na? Wa ma kalo, wa ma kalo, Wa si egbe ero wa, Wa, e ma se fi wa s

LOJO RE MIMO YI

Text: Elizabeth Parson, 1812-1873 Jesu, a fe pade, Lojo Re mimo yi; A si yite Re ka, Lojo Re mimo yi: 'Wo Ore wa orun, Adura wa n bo wa, Boju wo emi wa Lojo Re mimo yi. A ko gbodo lora, Lojo Re mimo yi Li eru a kunle Lojo Re mimo yi; Ma taro ise wa, K'Iwo ko si ko wa, Ka sin O bo ti ye Lojo Re mimo yi A teti soro Re Lojo Re mimo yi; Bukun oro ta gbo, Lojo Re mimo yi; Ba wa lo 'gbat'a lo, Fore igbala Re Si aya wa gbogbo, Lojo Re mimo yi.br /> Ese fi ewon de mi, Da mi, Oluwa da mi, Iwo ni n o sin titi, Jesu Olugbala mi. Jesus we love to meet On this Thy holy day We gather round Thy throne On this Thy holy day, Thou art our heavenly Friend Our prayers ascend to Thee Look on our spirits, Lord On this Thy Holy day. Let us shake off dull sloth On this Thy holy day. We kneel in reverence Lord On this Thy holy day. Our sins may Thou forgive And may Thou teach us, Lord To worship as we ought On this Thy holy day We listen t

EMI ORUN GBADURA WA

Words: Andrew Reed, 1829 Emi orun, gbadura wa, Wa gbenu ile yi Sokale pel'agbara Re, Wa, Emi Mimo wa. Wa b'imole, si fihan wa Baini wa ti po to; Wa, to wa si ona iye, Ti olododo n rin. Wa bi ina ebo mimo: Sokan wa di mimo; Je ki okan wa je ore, Foruko Oluwa. Wa bi iri, si wa bukun Akoko mimo yi: Ki okan alaileso wa Le yo l'agbara Re. Wa bi adaba, n'apa Re, Apa ife mimo; Wa je ki ijo Re laye Dabi ijo torun. Emi orun, gbadura wa, Saye yi dile Re; Sokale pel'agbara Re, Wa, Emi Mimo wa. Spirit divine, attend our prayers, and make this house thy home; descend with all thy gracious powers, O come, great Spirit, come! Come as the light; to us reveal our emptiness and woe, and lead us in those paths of life whereon the righteous go. Come as the fire and purge our hearts like sacrificial flame; let our whole soul an offering be to our Redeemer's Name. Come as the dove, and spread thy wings, the wings of peaceful love;

SI PEPE OLUWA

Author Unknown Si pepe Oluwa, Mo mu 'banuje wa; 'Wo ki o fanu tewogba Ohun alaiye yi? Kristi Odaguntan Ni igbagbo mi n wo; 'Wo le ko'hun alaiye yi? 'Wo o gba ebo mi. Gba ti Jesu mi ku, A te ofin lorun; Ofin ko ba mi leru mo, Tori pe Jesu ku. To the altar of my Lord, I bring all my sorrows, Can your mercy kindly accept me, Even this living soul? Jesus Christ the Lamb of God, All time depends on You, Will You reject this my living soul? Sacrifice Thou accept When Christ died for me, The fulfilment of law The law has no more power on me, Jesus has died for me. Source: Hymnaro #590 Aroyehun ©2013

WA, EYIN OLOPE WA

Words: Henry Alford, Psalms and Hymns, 1844 Wa, eyin olope wa, Gbe orin ikore ga: Ire gbogbo ti wole Kotutu oye to de: Olorun Eleda wa Lo ti pese faini wa Wa ka rele Oloru Gbe orin ikore ga. Oko Olorun laye, Lati so eso iyin Re: Alikama at'epo N dagba faro tab'ayo Ehu na, ipe tele, Siri oka, nikehin; Oluwa 'kore, mu wa Je eso rere fun O. Nitori Olorun wa n bo Yo si kore Re sile: On o gbon gbogbo panti Kuro loko Re n'jo na; Yo fase fawon Angel' Lati gba epo sina, Lati ko alikama Si aba Re titi lai. Beeni, ma wa, Oluwa Sikore ikehin; Ko awon eniyan Re jo Kuro lese ataro: So won di mimo lailai Ki won le ma ba O gbe: Wa t'Iwo t'Angeli Re Gbe orin ikore ga.br /> Come, ye thankful people, come, raise the song of harvest home; All is safely gathered in, ere the winter storms begin. God our Maker doth provide for our wants to be supplied; Come to God’s own temple, come, raise the song of harvest home. All the world is

IFE ORUN

Ife orun, o ti dun to! Gbawo ni n o ri t'okan mi Y'o kun fun kiki re? Okan mi n pongbe lati mo Riri ife irapada; Ife Kristi si mi. Ife Re n'ipa ju iku; Oro Re awamaridi! Awon Angeli paapaa Wa ijinle ife yi ti. Won ko le mo iyanu na, Giga ati'bu re. Olorun nikan l'O le mo, I ba je tan kale loni; L'okan okuta yi! Ife nikan ni mo n toro, Ko je ipin mi Oluwa: K'ebun yi je temi. Emi i ba le joko lai, Bi Maria, lese Jesu; Keyi je ayo mi; Ko janiyan atife mi, Ko si j'orun fun mi laye Lati ma gbohun Re. Source: YBH #266

WA BA MI GBE

By Henry F. Lite Wa ba mi gbe, ale fere le tan Okunkun su, Oluwa ba mi gbe Bi oluranlowo miran baye Iranwo alaini, wa ba mi gbe. Ojo aye mi n sare lo s'opin Ayo aye n ku, ogo re n womi Ayida at'ibaje ni mo n ri 'Wo ti ki yipada, wa ba mi gbe. Mo n fe ri O ni wakati gbogbo Ki lo le segun esu b'ore Re Ta lo le samona mi bi Re? N'nu banuje at'ayo, ba mi gbe. Pelu 'bukun Re, eru ko ba mi Ibi ko wuwo, ekun ko koro Oro iku da? Isegun isa da? N o segun sibe b'Iwo ba mi gbe. Ki n f'oro Re ni wakati iku Se'mole mi, si toka si orun B'aye ti n koja, kile orun mo Ni yiye, ni kiku, wa ba mi gbe. Source: YBH 599 Abide with me; fast falls the eventide; The darkness deepens; Lord with me abide. When other helpers fail and comforts flee, Help of the helpless, O abide with me. Swift to its close ebbs out life’s little day; Earth’s joys grow dim; its glories pass away; Change and decay in all around I see; O Thou who chan

JESU B'OLUSO MA A SIN WA

By Dorothy A. Thrupp Jesu b'Oluso ma a sin wa A n fe ike Re pupo F'ounje didara Re bo wa Tun agbo Re se fun wa Olugbala!  Olugbala! O ra wa. Tire l'a se O seleri lati gba wa Pel'ese at'aini wa: O lanu lati fi wo wa Ipa lati da wa n'de Olugbala!  Olugbala! A o wa o lakoko Je ka tete w'ojure Re Ka se'fe Re ni kutu Oluwa at'Olugbala Fife Re kun aya wa Olugbala!  Olugbala! O fe wa sibesibe. Saviour, like a shepherd lead us, Much we need Thy tender care; In Thy pleasant pastures feed us, For our use Thy folds prepare. Blessed Jesus, blessed Jesus! Thou hast bought us, Thine we are. Blessed Jesus, blessèd Jesus! Thou hast bought us, Thine we are. We are Thine, Thou dost befriend us, Be the guardian of our way; Keep Thy flock, from sin defend us, Seek us when we go astray. Blessèd Jesus, blessèd Jesus! Hear, O hear us when we pray. Blessèd Jesus, blessèd Jesus! Hear, O hear us when we pray. Thou hast promised to

MU WON WA

By Alexcenah Thomas Olusaguntan ni n pe mi Kuro nin'aginju ese O n paguntan to sako lo Jina rere sinu agbo Mu won wa, mu won wa Mu won wa kuro loko ese Mu won wa, mu won wa Masako wa sodo Jesu Ran Olusaguntan lowo Lati wa'aguntan Re to nu Mu awon to nu pada wa Sin'agbo kuro lotutu Gbo igbe won nin'aginju Ati lori oke giga Gb'Olusaguntan n wi fun o "Lo mu aguntan mi wole." Hark! ’tis the Shepherd’s voice I hear Out in the desert dark and drear, Calling the sheep who’ve gone astray Far from the Shepherd’s fold away. Bring them in, bring them in, Bring them in from the fields of sin; Bring them in, bring them in, Bring the wand’ring ones to Jesus. Who’ll go and help this Shepherd kind, Help Him the wand’ring ones to find? Who’ll bring the lost ones to the fold, Where they’ll be sheltered from the cold? Out in the desert hear their cry, Out on the mountains wild and high; Hark! ’tis the Master speaks to thee, “Go

YO AWON TI N SEGBE

By Fanny J Crosby Yo awon ti n segbe, sajo eni n ku Fanu ja won kuro ninu ese Ke fawon ti n sina, gbeni n subu ro So fun won pe Jesu le gba won la Yo awon ti n segbe, sajo eni n ku Alaanu ni Jesu, Yio gbala. Bi won o tile gan An, sibe O n duro Lati gb'omo to ronupiwada Sa fitara ro won, si ro won jeje On o dariji, bi won ba gbagbo Refrain Yo awon ti n segbe,--ise tire ni Oluwa yio f'agbara fun o; Fi suuru ro won, pada sona tooro So fasako p'Olugbala ti ku. Refrain Rescue the perishing, care for the dying, Snatch them in pity from sin and the grave; Weep o’er the erring one, lift up the fallen, Tell them of Jesus, the mighty to save. Rescue the perishing, care for the dying, Jesus is merciful, Jesus will save. Though they are slighting Him, still He is waiting, Waiting the penitent child to receive; Plead with them earnestly, plead with them gently; He will forgive if they only believe. Down in the human heart, crushed by the tempter

ORE OFE OHUN

Words: Philip Doddridge (1702-1751) Ore ofe! Ohun Adun ni l’eti wa Gbongbon re y’o gba orun kan Aye y’o gbo pelu Ore ofe sa N’igbekele mi Jesu ku fun araye O ku fun mi pelu Ore ofe l’o ko Oruko mi l’orun L’o fi mi fun Od’agutan T’O gba iya mi je. Ore ofe to mi S’ona alafia O ntoju mi l’ojojumo Ni irin ajo mi Ore ofe ko mi Bi a ti ‘gbadura O pa mi mo titi d’oni Ko si je ki nsako Je k’ore ofe yi F’agbara f’okan mi Ki nle fi gbogbo ipa mi At’ojo mi fun O. Grace ! 'tis a charming sound, Harmonious to the ear ; Heaven with the echo shall resound, And all the earth shall hear. Saved by grace alone; This is all my plea- Jesus died for all mankind, And Jesus died for me. 'Twas grace that wrote my name In life's eternal book; 'Twas grace that gave me to the Lamb, Who all my sorrows took. Grace taught my wandering feet To tread the heavenly road ; And new supplies each hour I meet, While pressing on to God. Grace taught my s

ENI BA GBEKELE OLUWA

Ẹni ba gbẹkẹle Ọlọrun; L'abo l'ọrun at'aye; Ẹni ba f'ifẹ wo Jesu; Ko s'ẹru ti n daamu rẹ. L'ara rẹ nikan oluwa; Ni mo r'adun itunu; Asa f'ọta at'ogun mi; Igbala mi t'o daju.  Ninu ijakadi aye; L'emi o duro ṣinsin; 'Danwo yoo sọ ipa rẹ nu; Nitori 'wọ o ṣọ mi. Oluwa s'ẹri ibukun rẹ; S'ara ati ọkan mi; Jẹ t'emi si ṣe m'ni tirẹ; Nitori iku Jesu.

Jesu Yoo Joba

Words: Isaac Watts, 1719 Jesu y'o joba ni gbogbo Ibi ta ba le ri orun; 'Joba Re yo tan kakiri, 'Joba Re ki yo n'ipekun O'n la o ma gbadura si, Awon oba yo se l'Oba; Oruko Re b'orun didun, Yo ba ebo ooro goke. Gbogbo oniruru ede, Y'o f'ife Re ko'rin didun: Awon omode yoo jewo Pe 'bukun won todo Re wa. 'Bukun po nibit'O n joba: A tu awon onde sile Awon alare si simi Alaini si ribukun gba Ki gbogbo eda ko dide, Ki won f'ola fun Oba won: K'Angel' tun wa t'awon t'orin Ki gbogb'aye jumo gbe'rin. Jesus shall reign where e'er the sun doth his successive journeys run; his kingdom stretch from shore to shore, till moons shall wax and wane no more. To him shall endless prayer be made, and praises throng to crown his head; his Name like sweet perfume shall rise with every morning sacrifice. People and realms of every tongue dwell on his love with sweetest song; and infant

Olori Ijo T'orun

Image
Words: Charles Wesley (1707-1788) Olori ijo torun Layo la wole fun O; K'O to de ijo t'aye Y'o ma korin bi torun A gbe okan wa soke Nireti to nibukun Awa kigbe, awa fiyin F'Olorun igbala wa. Bi a wa ninu 'ponju, T'a n koja ninu ina, Orin ife lawa o ko Ti yoo mu wa sun mo O Awa sape, a si yo Ninu ojurere Re Ife to so wa di tire Yoo pa wa mo titi lai. Iwo mu awon eeyan Re Koja isan idanwo A ki o beru wahala 'Tori O wa nitosi Aye, ese at'Esu, Koju ija si wa lasan Lagbara Re a o segun A o si korin Mose. Awa figbagbo rogo T'O n fe lati fi wa si A kegan ere aye Ti a fi siwaju wa Bi o ba si ka wa ye Awa pelu Stefen t'o ku Yoo ri O bo ti duro Lati pe wa lo sorun Head of Thy Church triumphant, We joyfully adore Thee; Till Thou appear, Thy members here Shall sing like those in glory. We lift our hearts and voices With blest anticipation, And cry aloud, and give to God The praise of our salvation. While in

JESU N PE WA

Image
Author: Cecil Frances Alexander (1852) Jesu npe wa l' osan, l' oru Larin irumi aiye; Lojojumo l' a ngb' ohun Re Wipe, "Kristian, tele Mi." Awon Apostili 'gbani, Ni odo Galili ni; Nwon ko ile, ona sile, Gbogbo nwon si nto lehin. Jesu npe wa larin lala Aiye wa buburu yi; Larin Afe aiye, O nwi Pe, "Kristian, e feran Mi." Larin ayo at' ekun wa, Larin 'rora on osi, Tantan L' O npe l' ohun rara Pe, "Kristian, e feran Mi." Olugbala, nip' anu Re, Je ki a gbo ipe Re, F' eti 'gboran fun gbogbo wa, K' a fe O ju aiye lo. Jesus calls us: o'er the tumult Of our life's wild, restless sea; Day by day his sweet voice soundeth Saying, "Christian, follow me." As, of old, apostles heard it By the Galilean lake, Turned from home and toil and kindred, Leaving all for his dear sake. Jesus calls us from the worship Of the vain world's golden store, From each idol t

E WOLE FOBA

Words: Robert Grant E wole f'Oba, Ologo julo E korin ipaati ife Re Alabo wa ni, at'Eni Igbani O n gbenu ogo, Eleru ni iyin E so tipa Re, e so t'ore Re 'Mole laso Re, gobi Re orun B'ara ti n san ni keke ibinu Re Ipa ona ni a ko si le mo Aye yii pelu ekun re gbogbo Olorun, agbara Re lo da won O fi idi re mule, ko si le yi O si f'okun se oja igbaya re Itoju Re wa lara gbogbo won Ninu afefe, ninu imole Itoju Re wa nin'odo ti o n san O si wa ninu iri ati ojo Awa erupe, aw'alailera 'Wo la gbekele, O ki o da ni Anu Re ronu, o si le de opin Eleda, Alabo, Olugbala wa. 'Wo Alagbara, Onife julo B'awon angeli, ti nyin O loke Be lawa eda Re, niwon ta le se A o ma juba Re, a o ma yin O Oh, worship the King, all-glorious above, Oh, gratefully sing His pow’r and His love; Our Shield and Defender, the Ancient of Days, Pavilioned in splendor, and girded with praise. Oh, tell of His might, oh, sing of His grace, Whose r

E FI IYIN FUN OLORUN

Text: Thomas Ken E fi iyin fun Olorun E yin, eyin eda aye E yin eyin eda orun Yin Baba, Omo on Emi. Praise God, from whom all blessings flow; Praise Him, all creatures here below; Praise Him above, ye heav’nly host; Praise Father, Son, and Holy Ghost! Praise God the Father who’s the source; Praise God the Son who is the course; Praise God the Spirit who’s the flow; Praise God, our portion here below!

EYIN TE FE OLUWA

Text: Isaac Watts Eyin t'e fe Oluwa E fi ayo yin han E jumo ko orin didun/2x K'e si y'ite na ka/2x A n yan lo si Sion Sion t'o dara julo A n yan goke lo si Sion Ilu Olorun wa Awon ti ko korin Ni ko m'Olorun wa Sugbon awa omo Oba/2x Yio so ayo won ka/2x Oke Sion n mu Egberun adun wa Ki a to de gbangba orun/2x Pelu ita wura/2x Nje k'a maa korin lo K'omije gbogbo gbe A n yan n'ile Emmanuel/2x Saye didan loke/2x Source: Yoruba Baptist Hymnal #285 Come, ye that love the Lord, And let your joys be known; Join in a song with sweet accord, And thus surround the throne. We’re marching to Zion, Beautiful, beautiful Zion; We’re marching upward to Zion, The beautiful city of God. The sorrows of the mind Be banished from the place; Religion never was designed To make our pleasures less. Let those refuse to sing, Who never knew our God; But children of the heav’nly King May speak their joys abroad. The men of grace hav