Posts

Showing posts from 2017

Ma Toju Mi, Jehofah Nla

Author:  William Williams Pantycelyn Ma toju mi, Jehofah nla, Ero l' aiye osi yi, Emi ko l' okun, iwo ni, F' ow' agbara di mi mu, Ounje orun, ounje orun Ma bo mi titi lailai. S' ilekun isun ogo ni, Orisun imarale; Jeki imole Re orun Se amona mi jale; Olugbala, Olugbala S' agbara at' asa mi Gba mo ba te eba Jordan' Da ajo eru mi nu, Iwo t' O ti segun iku, Mu mi gunle Kenaan je; Orin iyin L' emi o fun O titi. Source: Yoruba Baptist Hymnal #335 Guide me, O Thou great *Jehovah, [*Redeemer] Pilgrim through this barren land; I am weak, but Thou art mighty, Hold me with Thy pow’rful hand. Bread of heaven, Bread of heaven, Feed me now and evermore Feed me now and evermore Open now the crystal fountain, Whence the healing stream doth flow; Let the fire and cloudy pillar Lead me all my journey through. Strong Deliv’rer, strong Deliv’rer, Be Thou still my Strength and Shield; Be Thou still my Strength and Shi

Mo Yo Pupo Pe Jesu Fe Mi

Author:  Philip P Bliss Mo yo pipo pe Baba wa orun So t'ife Re ninu 'we t'o fun mi, Mo r' ohun 'yanu ninu Bibeli, Eyi sowon ju pe Jesu fe mi, Egbe Mo yo pipo pe Jesu fe mi, Jesu fe mi, Jesu fe mi, Mo yo pipo pe Jesu fe mi, Jesu fe an' emi. Gba mo gbagbe Re, ti emi salo O fe mi sibe, O wa mi kiri, Mo yara pada s' apa anu Re, 'Gbati mo ranti pe Jesu fe mi. Bi o se orin kan l' emi le ko, 'Gba mo r' Oba nla ninu ewa Re, Eyi yio ma j'orin mi titii, A! iyanu nipe Jesu fe mi. Jesu fe mi mo si mo pe mo fe E, Ife l'o m' U wa r' okan mi pada, Ife lo m' U ko ku l' ori igi, O da mi loju pe Jesu fe mi. Emi o ti se dahun b' a bi mi Ohun ti Ogo Oluwa mi je? Emi Mimo njeri nin' okan mi, Ni igbagbo pe Jesu fe mi. Ni igbekele yi mo r' isimi, Ni 'gbekele Krist, mo d' alabukun, Satan damu sa kuro l' okan mi, Nigba mo so fun pe Jesu

Niboji la t'E si/ Low In The Grave He Lay

Author: Robert Lowry Niboji la t'E si Jesu Olugbala  Jesu Oluwa mi 'Reti ojo naa Refrain: Nisa oku, Jesu ji!  Pelu 'segun lor' awon ota Re  O jinde pelu 'segun lor' okunkun O joba titi pel'awon eni mimo  Jesu ji,  Jesu ji, Halleluyah, O jinde!  Lasan won ṣọ 'busun Rẹ Jesu Olugbala Lasan won di oku Jesu Oluwa! Iku  ko le gbe E de Jesu Olugbala!  Jesu Oluwa mi Fo 'lekun irin  Translation by Biola Dada (Mrs) & Lanre Oyedokun, August 2016 Low in the grave He lay, Jesus my Savior,  waiting the coming day,  Jesus my Lord!  Refrain:  Up from the grave He arose;  with a mighty triumph o'er his foes;  He arose a victor from the dark domain,  and He lives forever, with his saints to reign.  He arose! He arose!  Hallelujah! Christ arose!  Vainly they watch His bed,  Jesus my Savior,  vainly they seal the dead,  Jesus my Lord!  Death cannot keep its prey,  Jesus my Savior;  He tore the bars away,  Jesus my L

Ko Je Gbagbe Mi

Author: Evangelist D.O Babajide Ore bi Jesu ko si laye yi Oun nikan l'ore otito Ore aye yi le ko wa sile Sugbon Jesu ko je gbagbe wa Ah! Ko je gbagbe wa/ 2ce Sugbon Jesu ko je gbagbe wa Akoko nkoja lo laifotape A f ojo kan sunmole wa si Onidajo mbo gongo yio so Awawi kan kosi l ojo na Duro d'Oluwa, ma siyemeji Ohunkohun t' o wu ko le de Gbat o ro p'o pin ranwo Re y'o de Eni yanu l oba Oluwa There is no friend like Jesus in the world Jesus is the only sincere friend The friend of this world will one day leave us But the Lord will never forget us He'll never forget us/2ce But the Lord will never forget us Not caring for foes, the time is passing Drawing near to our home day by day The Great Judge will come  the earth will tremble There will be no excuse on the day Now, wait on the Lord, never doubt again Whatever now may betide thee When there's no more hope, then His help will come Our Lord Jesus is a wonderful King 

A nsoro ile bukun ni

Writer:  Elizabeth K. Mills A nsoro ile bukun ni Ile didan atile ewa N'gba gbogbo la nso togo re Yo ti dun to lati de 'be! A nsoro ita wura re Oso odi re ti ko legbe Faji re ko se fenu so Yo ti dun to lati de 'be! A n so pese ko si nibe Ko saniyan at'ibanuje Pelu 'danwo lode ninu Yo ti dun to lati de 'be A soro orin iyin re Ti a ko le forin aye we, Bo ti wu korin wa dun to Yo ti dun to lati de 'be! A n soro isin ife re Ti agbada tawon mimo nwo Ijo akobi ti oke Yo ti dun to lati de 'be! Jo Oluwa tibi tire Sa se emi wa ye fun orun Laipe awa na yio mo Bo ti dun to lati de 'be Source: Yoruba Baptist Hymnal #535 We speak of the realms of the Blest, Of that country so bright and so fair, And oft are its glories confessed; But what must it be to be there? We speak of its pathways of gold, Of its walls decked with jewels most rare, Its wonders and pleasures untold; But what must it be to be there? We speak o

Baba, Mo N'owo Mi Si O

Writer: Charles Wesley Baba, mo n' owo mi si O; Nko mo 'ranwo miran: Bi O ba kuro lodo mi, A! nibo ni ngo lo? Ohun t' OmoRe f' ara da Ki nto la 'ju s' aiye! Ise t' O se lati gba mi Lowo 'ku ailopin! Orisun 'gbagbo, si O ni Mo gb' oju are mi: Mba je le ri ebun ni gba Laisi re mo segbe. Source: Yoruba Baptist Hymnal #220 Father, I stretch my hands to Thee, No other help I know; If Thou withdraw Thyself from me, Ah! Whither shall I go? On Thy dear Son I now believe O let me feel Thy power And all my varied wants relieve In this accepted hour Author of faith! to Thee I lift My weary longing eyes O let me now receive this gift My soul without it dies Surely Thou canst not let me die; O speak, and I shall live; And here I will unwearied lie, Till Thou Thy Spirit give. How would my fainting soul rejoice Could I but see Thy face Now let me hear Thy quickening voice And taste Thy pardoning grace I do b

Ojo 'Dajo, Ojo Eru

Author: John Newton (1774) Ojo 'dajo, ojo eru! Gbo bi ipe tin dun to! O ju egbarun ara lo, O sin mi gbogbo aiye. Bi esun na Yio ti damu elese. Wo Onidajo l' awo wa, O woo go nla l' aso, Gbogbo wa ti now ona Re, Gbana ni nwon o ma yo. Olugbala, Jewo mi ni ijo na. Ni pipe Re, oku yio ji Lat' okun, ile, s' iye Gbogbo ipa aiye yio mi, Nwon o salo l' oju Re, Alaironu, Yio ha ti ri fun O? Sugbon f'a won t' o jewo Re, T' nwon fe, tin won sin l' aiye, Yio pe, "Wa, alabukunfun; Wo ' joba ti Mo fun nyin, Titi aiye, L'e o mo 'fe at' ogo Mi." Source: Baptist Hymnal #521 Day of judgment! Day of wonders! Hark! the trumpet’s awful sound, Louder than a thousand thunders, Shakes the vast creation round! How the summons wilt the sinner’s heart confound! See the Judge, our nature wearing, Clothed in majesty divine! You who long for His appearing Then shall say, “Th

E BA WA YIN OLUWA, ALLELUYA!

Image
Eni t'O f'orun sile t'O wa s'aye Lati ku fun ese araye gbogbo; E korin aleluya s'Oba mimo Eni ba more Jesu ko ba wa gbe ga. Refrain: E ba wa yin Oluwa,  Aleluya! Eni ba more Jesu ko ba wa gbe ga, E ba wa yin Oluwa,  Aleluya! Eni ba more Jesu ko ba wa gbe ga, Eni ba more Jesu ko ba wa gbe ga. E ba wa yin Oluwa,  Aleluya! Eni ba more Jesu ko ba wa gbe ga. Eni t'O pa wa mo o lojojumo, Eni t'O n yo wa ninu ewu gbogbo Eni t'O n pa Israeli mo k'itogbe Eni ba more Jesu ko ba wa gbe ga. Eni t'O n pese fun aini wa laye, Eni t'O n sore fun wa lojo gbogbo, Ore t'O n se fun wa ko l'onka rara; Eni ba more Jesu ko ba wa gbe ga. He who left heav'n and came into the world And to die for the sins of all the people Sing hallelujah unto the holy King He who knows the goodness of Jesus should praise Him. Refrain: Come and let us praise the Lord, Hallelujah! He who knows the goodness of Jesus should praise Him

Jesu O Seun/ Jesus Thank You

Writer:Pat Sczebel Adiitu agbelebu ko ye mi sibẹ, Irora ti Kalfari-- Ìwọ t'O pe t'O si mọ lu Ọmọ Rẹ T'O m'ago ikoro to yẹ ki n mu. Chorus Ẹ̀jẹ̀ Rẹ ti wẹṣẹ mi nu, Jesu O seun. Irunu Ọlọrun walẹ pata, Jesu O seun. Mo ti jọta Rẹ ri, Wayi mo n ba Ọ jeun, Jesu O seun. Nipa 'rubọ pipe Rẹ la fi fa mi, O s' ọta Rẹ dọrẹ Rẹ; Ọrọ or'ọfẹ ologo Rẹ lo tu jade, Aanu at' inu're Rẹ ko lopin. Bridge Olufẹ́ ọkan mi, Mo fẹ́ ma wa fun Ọ. Translated by Ayobami Temitope  Kehinde (21/04/2017) The mystery of the cross I cannot comprehend The agonies of Calvary-- You the perfect Holy One, crushed Your Son, Who drank the bitter cup reserved for me. CHORUS Your blood has washed away my sin Jesus, thank You The Father’s wrath completely satisfied Jesus, thank You Once Your enemy, now seated at Your table Jesus, thank You By Your perfect sacrifice I’ve been brought near, Your enemy You’ve made Your friend; Pouring out the riches of Yo

Lojoojo, Oluwa/ Day By Day, Dear Lord

Image
Author:Richard of Chichester (1197 – 3 April 1253) Lojoojo, Oluwa Ohun meta mo beere K'emi le ri O sii Ki n le nife Re sii K'emi le tele O sii Lojoojo Translation by Ayobami Temitope (19/04/2017) Day by day, dear Lord of you Three things I pray: To see you more clearly, To love you more dearly, To follow you more nearly, Day by day. Source here

Olurapada, Olugbala, Ore/ Redeemer, Saviour, Friend

Image
Author: Darrell Evans Mo mo pe mo wa lokan Re 'Gba t'O gori oke lo 'Tor' O foju ayérayé ri mi 'Gba mo si wa'nu ese Olurapada, Olugbala, Ore Refrain: Olurapada, tun r'okan mi pada Olugbala, wa bo mi ki n ma dese Iwo mo ailera mi O s'otito dopin Olurapada, Olugbala, Ore Gbogbo ina t'a fi b'eyin Re je At'egun to w' ori Re Iso ta kan mo'wo ailabawon So pe 'fe Re ko lopin Olurapada, Olugbala, Ore Tor' eyi or' ofe Re laye mi Yoo ma je fun iyin Re Pel'ayo n o f'awon ade mi lele F'oruko ta fi gba mi la(x2) Translated by Ayobami Temitope Kehinde (19/04/017) I know You had me on Your mind When You climbed up on that hill For You saw me with eternal eyes While I was yet in sin Redeemer, Saviour, Friend Refrain: Redeemer redeem my heart again Savior come and shelter me from sin You're familiar with my weakness Devoted to the end Redeemer, Saviour, Friend Every stripe

Emi Anu, Oto, Ife/ Spirit of Mercy, Truth And Love

Author Unknown Emi anu, oto, ife, Ran agbara Re t' oke wa; Mu iyanu ojo oni, De opin akoko gbogbo. Ki gbogbo orile-ede, Ko orin ogo Olorun, Ki a si ko gbogbo aiye, N' ise Olurapada wa. Olutunu at' Amona, Joba ijo enia Re, K'araiye mo ibukun Re, Emi anu, oto, ife. Source: Baptist Hymnal #156 Spirit of mercy, truth and love, O shed Thine influence from above, And still from age to age convey The wonders of this sacred day. Be God’s amazing glory sung; Let all the listening earth be taught The wonders by our Savior wrought. Still o’er Thy holy Church preside; Unfailing Comfort, heavenly  Guide, In every clime, by every tongue, Still let mankind Thy blessings prove, Spirit of mercy, truth and love. Source here .

Ogo Fun Olorun Baba/ Glory Be To God The Father

Author: Horatius Bonar Ogo fun Olorun Baba, Ogo f' Olorun Omo, Ogo fun Olorun Emi, Jehofa, Metalokan; Ogo, ogo. B' aiyeraiye ti nkoja. Ogo fun Enit' o few a, T' o we abawon wa nu; Ogo fun Enit' o ra wa, T' o mu wa ba Onj' oba; Ogo, ogo, Fun Od'-agutan t' a pa. "Ogo, 'bukun, iyin lailai!" L' awon ogun orun nko; "Ola, oro, ipa, 'joba!" L' awon eda fi nyin I, Ogo, ogo, Fun Oba awon oba. Source: Baptist Hymnal #157 Glory be to God the Father, Glory be to God the Son, Glory be to God the Spirit: Great Jehovah, Three in One! Glory, glory While eternal ages run! Glory be to him who loved us, Washed us from each spot and stain; Glory be to him who bought us, Made us kings with him to reign! Glory, glory To the Lamb that once was slain! Glory to the King of angels, Glory to the Church’s King, Glory to the King of nations; Heaven and earth, your praises brin

A Fiyin Aiku Fun

Writer: Isaac Watts A f' iyin aiku fun 'Fe Olorun Baba, Fun itunu t' aiye, At' ireti t' orun: O ran 'Mo Re aiyeraiye Lati ku fun ese t' a da. T' Olorun Omo ni Ogo lailai pelu, T' o f' eje Re ra wa N'nu egbe ainipekun : O ye, O joba nisiyi, O si nri eso iya Re. Wole fun oruko, Olorun emi lai, Enit' agbara Re So elese d' aye: On l' o par' ise 'gbala wa, L' o si f' ayo orun k' okan. 'Wo Olodumare, L' ola ye titi lai, Eni Metalokan, T' O tobi, t' O l' ogo: Nibiti ipa ero pin, 'Gbagbo bori, ife sin yin. Source: Baptist Hymnal #158 We give immortal praise To God the Father’s love, For all our comforts here, And better hopes above; He sent His own eternal Son, To die for sins that man had done. To God the Son belongs Immortal glory too, Who bought us with His blood From everlasting woe: And now He lives, and now He r

Fun Aanu To Po B'iyanrin

Writer: John Newton Fun aanu t' o po b' iyanrin, Ti mo ngba lojojo Lat' odo Jesu Oluwa, Kili emi le tun? Kili ohun ti mo le fun un Lat' inu okan mi? Ese ti ba gbogbo re je, Ofo li o si je. Eyi l' ohun t' emi o se, F' ohun t' O se fun mi; Em' o mu ago igbala, Ngo kepe Olorun. Eyi l'ope ti mo le da, Emi osi, are; Ngo f' ebun Re se iyanju Lati ma bere si. Emi ko le sin b' o ti to, Nko n' ise kan t' o pe; Sibe ngo du ki nsogo pe Gbese mi l' o po ju. Source: Baptist Hymnal #303 For mercies, countless as the sands, Which daily I receive From Jesus, my Redeemer's hands, My soul what canst thou give? Alas! from such a heart as mine, What can I bring him forth? My best is stained and dyed with sin, My all is nothing worth. Yet this acknowledgment I'll make For all he has bestowed; Salvation's sacred cup I'll take And call

Halleluyah, Halleluyah

Writer:  Christopher Wordsworth (1807-1885), 1862 Halleluyah, Halleluyah, E gbe ohun ayo ga, E korin inudidun, K' e si yin olorun wa, Enit'a kan m'agbelebu, T' o jiya fun ese wa; Jesu Kristi Oba ogo Jinde kuro n'nu oku. Irin idabu se kuro Kristi ku, O sit un ye, O mu iye at aiku Wa l'oro ajinde Re; Krist' ti' segun, awa segun Nipa agbara nla Re, Awa o jinde pelu Re, A o ba wo 'nu ogo. Kristi jinde, akobi ni Ninu awon t' o ti sun, Awon yi ni y' o ji dide, Ni abo Re ekeji; Ikore ti won ti pon tan Nwon  nreti  Olukore, Eniti y'o mu won kuro, Ninu isa oku won. Awa jinde pelu Kristi T'O nfun wa l' ohun gbogbo Ojo, iri, ati ogo To ntan jade l' oju Re; Oluwa b' a ti wa l'aiye, Fa okan wa s'odo Re, K'awon maleka saw a jo, Ki  nwon  ko wa d,odo Re. Halleluyah, Halleluyah! Ogo ni fun Olorun; Halleluyah f' Olugbala Enit' Osegun iku.

Krist' Oluwa Ji Loni

Writer:  Charles Wesley Krist' Oluwa ji loni, - Halleluyah, Eda at' Angeli nwi - Hal. Gb' ayo at' isegun ga - Hal. K' orun at' aiye gberin! - Hal. Ise ti idande tan; - Hal. O jija, O ti segun; - Hal. Wo, 'ponju orun koja - Hal. Ko wo sinu eje mo - Hal. Lasan n' iso at' ami, - Hal. Krist' woo run apadi; - Hal Lasan l' agbara iku, - Hal. Krist, si Paradise. - Hal. O tun wa, Oba ogo: - Hal. "Iku itani re wa?" - Hal. Lekan l' O ku k' O gba wa, - Hal. "'Boji, isegun re wa?" - Hal. E je k' awa goke lo, - Hal. Sodo Kristi Ori wa, - Hal. A sa jinde pelu Re, - Hal. Bi a ti ku pelu Re. - Hal. Oluwa t' aiye t' orun, - Hal. Tire ni gbogbo iyin, - Hal. A wole niwaju Re - Hal. 'Wo Ajinde at' Iye. - Hal. Source: Baptist Hymnal #118 Christ the Lord is ris’n today, Alleluia! Sons of men and angels say, Alleluia! Raise your joys an

O KU! ORE ELESE KU / HE DIES! THE FRIEND OF SINNERS DIES!

Writer:  Isaac Watts O ku! - Ore elese ku; Omobirin Salem' sokun; Okunkun bo oju orun, Ile wariri lojiji. Ife at' ikanu l; eyi Oluwa Ogo ku f'enia! Sugbon ayo wo l'a ri yi - Jesu t' Oku tun ji dide! Olorun ko boji sile, O  lo s'agbala Baba Re. Ogun Angeli sin lo 'le, Nwon si fi ayo gba s' oke, Ma sokun mo, enyin mimo, K' e so giga ijoba Re; Korin b' O ti segun Esu, T' O si de iku li ewon. E wipe, "Oba wa titi, Enit' a bi lati gba la!" E b' iku pe, "Oro re da?" Isa-oku, "'Segun re da?" Source: Baptist Hymnal #119 He dies! the Friend of sinners dies! Lo! Salem’s daughters weep around; A solemn darkness veils the skies, A sudden trembling shakes the ground. Come, saints, and drop a tear or two For Him who groaned beneath your load: He shed a thousand drops for you, A thousand drops of richer blood. Here’s love and grief

E JE KA FINU DIDUN

Writer:  John Milton (1608-1674), 1623 E je k' a f' inu didun, Yin Oluwa Olore; Anu Re, o wa titi, L' ododo dajudaju. O'n, nipa agbara Re, F' imole s' aiye titun; Anu Re, o wa titi, L' ododo dajudaju. O mbo awon alaini, Ati gbogbo alaye; Anu Re, o wa titi, L' ododo dajudaju. O bukun ayanfe Re Li aginju iparun; Anu Re, o wa titi, L' ododo dajudaju. E je k' a f' inu didun, Yin Oluwa Olore; Anu Re, o wa titi, L' ododo dajudaju. Source: Baptist Hymnal #79 Let us, with a gladsome mind, praise the Lord, for he is kind: Refrain: for his mercies aye endure, ever faithful, ever sure. Let us blaze his Name abroad, for of gods he is the God: He with all commanding might filled the new-made world with light: He the gold-tressèd sun caused all day his course to run:  The horned moon to shine by night, mid her spangled sisters bright: All things livi